Mo ti yí ojú mi pẹ̀lú òtítọ́ inú síẸni tí ó ṣẹ̀dá àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,èmi kò sì wà lára àwọn tí ń fi alábàákẹ́gbẹ́ kún (Allāhu).Dájúdájú Sálàáh mi, ẹbọ mi,ìgbé ayé mi àti ikú mi jẹ́ ti Allāhu,Olúwa àwọn ayé, kò ní alábàákẹ́gbẹ́,pẹ̀lú èyí ni a pa mí láṣẹ,èmi sì wà lára àwọn Mùsùlùmí.Áà Allāhu, Ìwọ ni Ọba, kò sí ẹni tí ó yẹ láti júbà àyàfi Ìwọ.Ìwọ ni Olúwa mi, èmi sì ni ẹrú Rẹ,mo ti ṣe ara mi ní àìṣòdodo,mo sì ti gbà ẹ̀ṣẹ̀ mi,nítorí náà dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí,nítorí kò sí ẹni tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn àyàfi Ìwọ.Tọ́ mi sọ́nà sí ìwà tí ó dára jùlọ,nítorí kò sí ẹni tí ó lè tọ́ni sí i àyàfi Ìwọ,kí o sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà tí ó burú jùlọ,nítorí kò sí ẹni tí ó lè gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ̀ àyàfi Ìwọ.Wò mí níbí, ní ìdáhùn sí ìpè Rẹ, tayọ̀tayọ̀ ni mo fi sìn Ọ́.Gbogbo oore ń bẹ ní ọwọ́ Rẹ, ibi kò sì ti ọ̀dọ̀ Rẹ wá.Mo wà nípa ìfẹ́ Rẹ, èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ Rẹ.Ìbùkún àti gíga ni fún Ọ, mo tọrọ ìdáríjì Rẹ,mo sì ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ.Allāhu kì í ṣẹ̀dá ibi tí ó mọ́ gaaratí kò ní oore kankan tàbí tí kò ní anfààní,ọgbọ́n tàbí àánú kankan nínú rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kì í fi ìyà jẹ ẹnikẹ́ni láìsí pé ó ti dá ẹ̀ṣẹ̀.Nǹkan kan lè dára ní ti ìṣẹ̀dárẹ̀ nígbà tí a bá wò ó láti ibi kan,kí ó sì jẹ́ ibi nígbà tí a bá wò ó ní ọ̀nà mìíràn.Allāhu ṣẹ̀dá èṣù,àti nípasẹ̀ rẹ̀ ni Ó fi ń dán àwọn ẹrú Rẹ̀ wò,nítorí náà àwọn kan wà tí wọ́n kórìíra èṣù,tí wọ́n ń bá a àti ọ̀nà rẹ̀ jà,tí wọ́n sì dúró ní ọ̀tá sí i àti sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀,àwọn mìíràn sì wà tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìnsí èṣù tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ipasẹ̀ rẹ̀.Nítorí náà ibi wà láàrin àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ nípa ìfẹ́ àti ọgbọ́n Rẹ̀,kì í ṣe nínú àwọn ìṣe Rẹ̀ tàbí nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Rẹ̀.