Ọlá rírántí Allāhu
قَالَ صلى الله عليه وسلم مَنْ قَالَ: سُبْحَانَ اللَّهِ وَبِحَمْدِهِ فِي يَوْمٍ مِائَةَ مَرَّةٍ حُطَّتْ خَطَايَاهُ وَلَوْ كَانَتْ مِثْلَ زَبَدِ الْبَحْر)).
(Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé:(Mímọ́ ni Allāhu, mo sì yìn Ín.) ní ìgbà ọgọ́rùn-ún láàrin ọjọ́, a ó nu àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nù, kódà bí wọ́n bá dàbí ìfòfò òkun.)
وَقَالَ صلى الله عليه وسلم: ((مَنْ قَالَ لاَ إِلَهَ إِلاَّ اللَّهُ وَحْدَهُ لاَ شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ، وَلَهُ الْحَمْدُ، وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ عَشْرَ مِرَارٍ، كَانَ كَمَنْ أَعْتَقَ أَرْبَعَةَ أَنْفُسٍ مِنْ وَلَدِ إِسْمَاعِيلَ)).
(Abu Hurayrah sọ pé Òjíṣẹ́ Allāhu ﷺ sọ pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé: (Kò sí ẹni tí ó yẹ láti júbà àyàfi Allāhu nìkan ṣoṣo, láìní alábàákẹ́gbẹ́. Ti Rẹ̀ ni gbogbo ìjọba àti ìyìn, Òun sì ni Alágbára lórí ohun gbogbo.) ní ìgbà ọgọ́rùn-ún láàrin ọjọ́, yóò ní ẹ̀san ti dídá ẹrú mẹ́wàá sílẹ̀ lómìnira, a ó kọ ọgọ́rùn-ún iṣẹ́ rere sílẹ̀ fún un, a ó sì nu ọgọ́rùn-ún iṣẹ́ búburú nù, yóò sì ní ààbò kúrò lọ́wọ́ èṣù ní ọjọ́ náà títí di ìrọ̀lẹ́, kò sì sí ẹni tí yóò mú ohun tí ó sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ wá àyàfi ẹni tí ó ṣe jù ú lọ.)
وَقَالَ صلى الله عليه وسلم: ((كَلِمَتَانِ خَفِيفَتَانِ عَلَى اللِّسَانِ، ثَقِيلَتَانِ فِي الْمِيزَانِ، حَبِيبَتَانِ إِلَى الرَّحْمَنِ: سُبْحَانَ اللَّهِ وَبِحَمْدِهِ، سُبْحانَ اللَّهِ الْعَظِيمِ)).
(Abu Hurayrah sọ pé Òjíṣẹ́ Allāhu ﷺ sọ pé:’(Ọ̀rọ̀ méjì wà, (tí ó) fúyẹ́ lórí ahọ́n, tí ó wúwo lórí Òṣùwọ̀n, tí ó sì jẹ́ olùfẹ́ sí Aláàánú Jùlọ: (Mímọ́ ni Allāhu, mo sì yìn Ín. Mímọ́ ni Allāhu, Ẹni Ńlá.))
وَقَالَ صلى الله عليه وسلم: ((لَأَنْ أَقُولَ سُبْحَانَ اللَّهِ، وَالْحَمْدُ لِلَّهِ، وَلاَ إِلَهَ إِلاَّ اللَّهُ، وَاللَّهُ أَكْبَرُ، أَحَبُّ إِلَيَّ مِمَّا طَلَعَتْ عَلَيْهِ الشَّمسُ)).
(Abu Hurayrah sọ pé Òjíṣẹ́ Allāhu ﷺ sọ pé: ‘Sísọ pé: (Mímọ́ ni Allāhu, gbogbo ìyìn sì ni ti Allāhu. Kò sí ẹni tí ó yẹ láti júbà àyàfi Allāhu, Allāhu sì tóbi jùlọ.) wù mí ju gbogbo ohun tí oòrùn yọ lé lórí lọ.)
وَقَالَ صلى الله عليه وسلم: ((أَيَعْجِزُ أَحَدُكُم أَنْ يَكْسِبَ كُلَّ يَوْمٍ أَلْفَ حَسَنَةٍ)) فَسَأَلَهُ سَائِلٌ مِنْ جُلَسَائِهِ كَيْفَ يَكْسِبُ أَحَدُنَا أَلْفَ حَسَنَةٍ؟ قَالَ: ((يُسَبِّحُ مِائَةَ تَسْبِيحَةٍ، فَيُكتَبُ لَهُ أَلْفُ حَسَنَةٍ أَوْ يُحَطُّ عَنْهُ أَلْفُ خَطِيئَةٍ)).
(Saʿd sọ pé: ‘A jókòó pẹ̀lú Òjíṣẹ́ Allāhu ﷺ, ó sì sọ pé: ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú yín kò lè jèrè ẹgbẹ̀rún iṣẹ́ rere lójoojúmọ́?’ Ẹnìkan wá bi í léèrè pé: Báwo ni ènìyàn ṣe lè jèrè ẹgbẹ̀rún iṣẹ́ rere? Ó fèsì pé: ‘Kí ó sọ pé: (Mímọ́ ni Allāhu.) ní ìgbà ọgọ́rùn-ún, nítorí a ó kọ ẹgbẹ̀rún iṣẹ́ rere sílẹ̀ fún un tàbí a ó nu ẹgbẹ̀rún iṣẹ́ búburú nù.)
((مَنْ قَالَ: سُبْحَانَ اللَّهِ الْعَظِيمِ وَبِحَمْدِهِ غُرِسَتْ لَهُ نَخْلَةٌ فِي الْجَنَّةِ)).
(Jābir sọ pé Anọ́bì ﷺ sọ pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé: (Mímọ́ ni Allāhu, Ẹni Ńlá, mo sì yìn Ín.) a ó gbin igi ọ̀pẹ kan fún un ní Ọ̀run Rere.)
وَقَالَ صلى الله عليه وسلم: ((يَا عَبْدَ اللَّهِ بْنَ قَيْسٍ أَلاَ أَدُلُّكَ عَلَى كَنْزٍ مِنْ كُنُوزِ الْجَنَّةِ))؟ فَقُلْتُ: بَلَى يَا رَسُولَ اللَّهِ، قَالَ: ((قُلْ لاَ حَوْلَ وَلاَ قُوَّةَ إِلاَّ بِاللَّهِ)).
(ʿAbdullāh ọmọ Qays sọ pé Anọ́bì ﷺ sọ fún un pé: ‘ Áà ʿAbdullāh ọmọ Qays, ṣé kí n má sọ ìṣúra kan nínú àwọn ìṣúra Ọ̀run Rere fún ọ?’ Lẹ́yìn náà ó sọ pé: ‘Sọ pé: (Kò sí agbára tàbí ipá kankan àyàfi pẹ̀lú Allāhu.))
وَقَالَ صلى الله عليه وسلم: ((أَحَبُّ الْكَلاَمِ إِلَى اللَّهِ أَرْبَعٌ: سُبْحَانَ اللَّهِ، وَالْحَمْدُ لِلَّهِ، وَلاَ إِلَهَ إِلاَّ اللَّهُ، وَاللَّهُ أَكْبَرُ، لاَ يَضُرُّكَ بِأَيِّهِنَّ بَدَأتَ)).
(àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wù Allāhu jùlọ jẹ́ mẹ́rin: (Mímọ́ ni Allāhu, gbogbo ìyìn ni ti Allāhu. Kò sí ẹni tí ó yẹ láti júbà àyàfi Allāhu, Allāhu sì tóbi jùlọ.))(kò ṣe pàtàkì èwo nínú wọn ni o bá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú.)
جَاءَ أَعْرَابِيٌّ إِلَى رَسُولِ اللَّهِ صلى الله عليه وسلم فَقَالَ: عَلِّمْنِي كَلاماً أَقُولُهُ: قَالَ: ((قُلْ: لاَ إِلَهَ إِلاَّ اللَّهُ وَحْدَهُ لاَ شَرِيكَ لَهُ، اللَّهُ أَكْبَرُ كَبِيراً، وَالْحَمْدُ لِلَّهِ كَثِيراً، سُبْحَانَ اللَّهِ رَبِّ العَالَمِينَ، لاَ حَوْلَ وَلاَ قُوَّةَ إِلاَّ بِاللَّهِ الْعَزِيزِ الْحَكِيمِ)) قَالَ: فَهَؤُلاَءِ لِرَبِّي، فَمَا لِي؟ قَالَ: ((قُلْ: اللَّهُمَّ اغْفِرْ لِي، وَارْحَمْنِي، وَاهْدِنِي، وَارْزُقْنِي)).
(Saʿd ọmọ Abī Waqqās sọ pé ọkùnrin kan wá sọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu ﷺ, ó sì sọ fún un pé: ‘Kọ́ mi ní nǹkan kan tí èmi yóò máa sọ?’ Ó sọ pé: ‘Sọ pé: (Kò sí ẹni tí ó yẹ láti júbà àyàfi Allāhu nìkan ṣoṣo láìní alábàákẹ́gbẹ́. Allāhu tóbi jùlọ, ìyìn púpọ̀ sì ni ti Allāhu. Mímọ́ ni Allāhu, Olúwa àwọn ayé. Kò sí agbára tàbí ipá kankan àyàfi pẹ̀lú Allāhu, Ẹni Ọlá Gíga, Ọlọ́gbọ́n.) ọkùnrin náà wá sọ pé: ‘Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ti Olúwa mi, kí ni ti èmi?’ Ó fèsì pé: ‘Sọ pé:(Áà Allāhu, dárí jìn mí, ṣàánú fún mi, tọ́ mi sọ́nà kí o sì pèsè fún mi.))
كَانَ الرَّجُلُ إِذَا أَسْلَمَ عَلَّمَهُ النَّبيُّ صلى الله عليه وسلم الصَّلاَةَ ثُمَّ أَمَرَهُ أَنْ يَدْعُوَ بِهَؤُلاَءِ الْكَلِمَاتِ: ((اللَّهُمَّ اغْفِرِ لِي، وَارْحَمْنِي، وَاهْدِنِي، وَعَافِنِي وَارْزُقْنِي)).
(Ṭāriq Al-Ashjaʿī sọ pé: ‘Nígbà tí ẹnìkan bá gba Ìsìláàmù, Anọ́bì ﷺ máa ń kọ́ ọ bí a ṣe ń kírun, lẹ́yìn náà yóò pa á láṣẹ láti ṣe àdúà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: (Áà Allāhu, dárí jìn mí, ṣàánú fún mi, tọ́ mi sọ́nà, fún mi ní ìlera kí o sì pèsè fún mi.))
((إِنَّ أَفْضَلَ الدُّعَاءِ الْحَمْدُ لِلَّهِ، وَأَفْضَلَ الذِّكْرِ لاَ إِلَهَ إِلاَّ اللَّهُ)).
(Jābir ọmọ ʿAbdullāh sọ pé Òjíṣẹ́ Allāhu ﷺ sọ pé: ‘Dájúdájú, àdúà tí ó dára jùlọ ni: (Gbogbo ìyìn ni ti Allāhu.) dájúdájú, ìrántí tí ó dára jùlọ sì ni: (Kò sí ẹni tí ó yẹ láti júbà àyàfi Allāhu.))
الباقيات الصالحات : سبحان الله والحمد لله ، ولا إله إلا الله ،والله أكبر ،و لا حول ولا قوة إلا بالله
Àwọn iṣẹ́ rere tí ó wà pẹ́ ni ‘Ògo ni fún Allāhu’, àti ‘Ìyìn ni ti Allāhu’, àti ‘Kò sí ẹni tí ó yẹ láti júbà àyàfi Allāhu’, àti ‘Allāhu ni Ẹni Ńlá Jùlọ’, àti ‘Kò sí agbára àti ipá àyàfi nípasẹ̀ Allāhu’