((اللَّهُمَّ إِنِّي عَبْدُكَ، ابْنُ عَبْدِكَ، ابْنُ أَمَتِكَ، نَاصِيَتِي بِيَدِكَ، مَاضٍ فِيَّ حُكْمُكَ، عَدْلٌ فِيَّ قَضَاؤُكَ، أَسْأَلُكَ بِكُــــلِّ اسْمٍ هُوَ لَكَ، سَمَّيْتَ بِهِ نَفْسَكَ، أَوْ أَنْزَلْتَهُ فِي كِتَابِكَ، أَوْ عَلَّمْتَهُ أَحَداً مِنْ خَلْقِكَ، أَوِ اسْتَأْثَرْتَ بِهِ فِي عِلْمِ الغَيْبِ عِنْدَكَ، أَنْ تَجْعَلَ القُرْآنَ رَبِيعَ قَلْبِي، وَنُورَ صَدْرِي، وَجَلاَءَ حُزْنِي، وَذَهَابَ هَمِّي)).
(Áà Allāhu, èmi ni ẹrú Rẹ, ọmọ ẹrú Rẹ ọkùnrin, ọmọ ẹrú Rẹ obìnrin, ìdí orí mi wà ní ọwọ́ Rẹ (ìyẹn ni, Ìwọ ní àkóso pátápátá lórí mi), àṣẹ Rẹ lórí mi ń ṣẹ nígbà gbogbo, ìdájọ́ Rẹ lórí mi sì jẹ́ òdodo. Mo bẹ̀ Ọ́ nípasẹ̀ gbogbo orúkọ tí ó jẹ́ Tìrẹ, èyí tí O fi sọ ara Rẹ lórúkọ, tàbí tí O sọ̀kalẹ̀ nínú Ìwé Rẹ, tàbí tí O kọ́ ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀dá Rẹ, tàbí tí O pamọ́ sínú ìmọ̀ àwọn ohun àìrí lọ́dọ̀ Rẹ, pé kí O ṣe Kùránì ní ìyè ọkàn mi àti ìmọ́lẹ̀ àyà mi, àti ìyọkúrò ìbànújẹ́ mi àti ìtúsílẹ̀ àníyàn mi.)