((لاَ بأْسَ طَهُورٌ إِنْ شَاءَ اللَّهُ)).
(Má ṣe fòyà, kí ó (àìsàn náà) jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́, tí Allāhu bá fẹ́.)
Àdhkār 4
((لاَ بأْسَ طَهُورٌ إِنْ شَاءَ اللَّهُ)).
(Má ṣe fòyà, kí ó (àìsàn náà) jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́, tí Allāhu bá fẹ́.)
((أَسْأَلُ اللَّهَ الْعَظيمَ رَبَّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ أَنْ يَشْفيَكَ)) (سبع مرات).
(Mo bẹ Allāhu Ẹni Ńlá, Olúwa ìtẹ́ ọlá ńlá, pé kí ó mú ọ lára dá’.(ìgbà méje) (a ó mú un (aláìsàn náà) lára dá.))
((اللَّهُ أَكْبَرُ، اللَّهُمَّ أَهِلَّهُ عَلَيْنَا بِالْأَمْنِ وَالْإِيمَانِ، وَالسَّلاَمَةِ وَالْإِسْلاَمِ، وَالتَّوْفِيقِ لِمَا تُحِبُّ رَبَّنَا وَتَرْضَى، رَبُّنَا وَرَبُّكَ اللَّهُ)).
(Allāhu tóbi jùlọ. Áà Allāhu, jẹ́ kí òṣùpá tuntun yìí yọ sí wa pẹ̀lú ààbò, ìgbàgbọ́, àlàáfíà àti Ìsìláàmù, àti ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí O fẹ́ tí ó sì tẹ́ Ọ lọ́rùn. Olúwa wa àti Olúwa yín ni Allāhu.)
((اللَّهُمَّ صَيِّباً نَافِعاً)).
(Áà Allāhu, jẹ́ kí ó jẹ́ àwọsánmọ̀ òjò tí ó ṣàǹfààní.)
Àwọn Àdúà fún àwọn àkókò tó ń yọjú láàrín ọdún.
Orísun: Hisn al-Muslim (Odi Mùsùlùmí). Ọ̀rọ̀ Lárúbáwá pẹ̀lú ìtumọ̀.
A mú wọn láti Hisn al-Muslim, àkójọ Àdhkār àti Àdúà láti inú Kùránì àti Sunnah tó jẹ́ òótọ́.
A fi iye náà hàn lókè Dhikr kọ̀ọ̀kan. Níbi tí a kò ti fi iye hàn, a máa ń sọ ọ́ lẹ́ẹ̀kan.