([بِسْمِ اللَّهِ] اللَّهُمَّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ مِنَ الْخُبْثِ وَالْخَبائِث).
((Ní orúkọ Allāhu). Áà Allāhu, mo sá di Ọ́ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ibi àti àwọn aṣebi.)
Àdhkār 6
([بِسْمِ اللَّهِ] اللَّهُمَّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ مِنَ الْخُبْثِ وَالْخَبائِث).
((Ní orúkọ Allāhu). Áà Allāhu, mo sá di Ọ́ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ibi àti àwọn aṣebi.)
(غُفْرَانَكَ).
(Mo tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Rẹ (Allāhu).)
(بِسْمِ اللَّهِ).
(Ní orúkọ Allāhu.)
(أَشْهَدُ أَنْ لاَ إِلَهَ إِلاَّ اللَّهُ وَحْدَهُ لاَ شَرِيكَ لَهُ وَأَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّداً عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ..).
(Mo jẹ́rìí pé kò sí ẹni tí ó yẹ láti júbà àyàfi Allāhu nìkan ṣoṣo láìní alábàákẹ́gbẹ́, mo sì jẹ́rìí pé Muhammad jẹ́ ẹrú Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀.)
(اللَّهُمَّ اجْعَلْنِي مِنَ التَّوَّابِينَ وَاجْعَلْنِي مِنَ الْمُتَطَهِّرِينَ)
(Áà Allāhu, ṣe mí ní ara àwọn tí ó máa ń padà sọ́dọ̀ Rẹ nínú ìrònúpìwàdà, kí o sì ṣe mí ní ara àwọn tí ó máa ń wà ní mímọ́ àti ní ìmọ́tótó.)
(سُبْحانَكَ اللَّهُمَّ وَبِحَمْدِكَ، أَشْهَدُ أَنْ لاَ إِلَهَ إِلاَّ أَنْتَ، أَسْتَغْفِرُكَ وَأَتوبُ إِلَيْكَ).
(Mímọ́ ni Ọ́, Áà Allāhu, mo sì yìn Ọ́, mo jẹ́rìí pé kò sí ẹni tí ó yẹ láti júbà àyàfi Ìwọ, mo tọrọ ìdáríjì Rẹ, mo sì ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ.)
Ìrántí kúkúrú fún àwọn àkókò ojoojúmọ́ ti ìmọ́tótó àti ìmúrasílẹ̀ fún Sálàáh.
Orísun: Hisn al-Muslim (Odi Mùsùlùmí). Ọ̀rọ̀ Lárúbáwá pẹ̀lú ìtumọ̀.
A mú wọn láti Hisn al-Muslim, àkójọ Àdhkār àti Àdúà láti inú Kùránì àti Sunnah tó jẹ́ òótọ́.
A fi iye náà hàn lókè Dhikr kọ̀ọ̀kan. Níbi tí a kò ti fi iye hàn, a máa ń sọ ọ́ lẹ́ẹ̀kan.